Ayé Ti Èrèdí Ńtukọ̀ Rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye ètò ìyanu Ọlọ́run fún ọ ní orí ilé ayé níbí àti fún ayérayé. Rick Warren yóò tọ́ ọ sọ́nà nípasẹ̀ ìrìn-àjò ogójì (40) Ọjọ́ ti ẹ̀mí kan tí yóò dáhùn ìbéèrè, “Kínni mo wà lórí ilé-ayé níbí fún?” Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ìwọ yóò kọ́ síwájú si nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá rẹ ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ fún èrèdí tí ìwọ nìkan lè múṣẹ.
Ayé Ti Èrèdí Ńtukọ̀ Rẹ̀ ńpèsè ọgbọ́n láti inú Bíbélì tí yóò kọ́ ọ ní ìdí tí ayé rẹ ṣe ṣe pàtàkì. Yóò fi hàn ọ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dín wàhálà rẹ kù, tẹjú agbara rẹ mọ́ nǹkan, mú àwọn ìpinnu rẹ rọrùn, kí ó sì pèsè rẹ sílẹ̀ fún ayérayé. Ó jẹ́ ìwáásù tí kò ní òdiwọ̀n àkókò tí yóò ṣí ọkàn rẹ payá tí yóò sì ru ọ́ lọ́kàn sókè láti gbé ayé tí ó ní àpẹẹrẹ.
RICK WARREN ni olùṣọ́-àgùtàn olùdásílẹ̀ ti Ìjọ Saddleback ní Gúsù California pẹ̀lú àwọn yàrá-ìkàwé ní àwọn olú ìyá-ìlú káàkiri agbáyé. Òun ni òǹkọ̀wé Ayé Ti Èrèdí Ńtukọ̀ Rẹ̀, èyítí a ti túmọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè tí ó sì ti ta àwọn ẹ̀dà tí ó ju mílíọ́nù àádọ́ta (50) lọ ní oríṣiríṣi ẹ̀yà.
The Purpose Driven Life will help you understand God’s amazing plan for you here on earth and for eternity. Rick Warren will guide you through a 40-Day spiritual journey that will help you answer the question, “What on earth am I here for?” Each day you will learn more about how God uniquely created you for a purpose only you can fulfill.
The Purpose Driven Life offers wisdom from the Bible that will teach you why your life matters. It will show you how God wants to help reduce your stress, focus your energy, simplify your decisions, and prepare you for eternity. It’s a timeless message that will inspire and motivate you to live a life of significance.
RICK WARREN is the founding pastor of Saddleback Church in Southern California with campuses in major cities around the world. He is the author of The Purpose Driven Life, which has been translated into many languages and sold more than 50 million copies in all formats.